A gbo pe ,won fi iwe s'owo si Osile Oke Ona Egba,Oba Dokita Adedapo Tejuosho lati mo si i,ki won to fi sowo si ijoba ipinle Ogun ti won si ko akole leta naa bayii'Wiwa aye si ipo oba to sofo ni Orile Ilawo''won so o sibe pe,gege bi ase tawon gba lati ileese to n ri si ijoba ibile ati Oye jije pelu Ofiisi Gomina pelu nomba CHM11/4/145 OF lojo kejilelogun osu kejo odun 2022 ati CHM11/4/1154 ti ojo mokandinlogbon osu kesan odun yii bakanna lati gbe igbese ona abayo si ipo oba to sofo naa, ati pe ijoba ipinle naa fowo si i pe ki awon afobaje mesan an seto oba laarin ojo merinla.
Ojo ketala osu kewa odun yii ni ipade naa waye ni adugbo Kegunmela iyen Ile Oloye Olufade Anthony Ajayi lati yan oba tuntun fun ilu Orlie Ilawo,nibe ni won ti so pe,gbogbo omo bibi ilu Orile Ilawo ti yan Oloye Olusegun Alexander MacGregor.
Ogbeni Kasimaawo Aremu Bakare to je akowe agbegbe Abelu Ilawo lo dabaa nigbati Arabinrin Kadijat Badejo sikeji ti awon to ku naa si fowo si i .A gbo pe ,eniti won Jo n du ipo oba ko yoju lo mu Osi Ilawo ni ki won dibo ti Oloye MacGregor si jawe olubori pelu ibo mefa Ni eyi to ka a ye gege bii oba alade fun ilu Orile Ilawo,to si ti gba iwe eri.
Omowe ati olopolo pipe ni oba tuntun fun ilu Orile Ilawo eyi lo mu ki Inu tomode tagba ilu naa n dun kiri titi di asiko yii.


No comments:
Post a Comment