Sugbon o je ohun iyalenu pe,awon kan ti dide lati ba oruko oba alade naa je,Koda Balogun ilu Ilawo iyen Oloye Abraham Adebayo Soyoye ti n so kiri pe,oba MacGregor n fi awon omoota atawon eso alaabo da ilu ru ati pe kabiesi n dunkoko mo oun lati dana sun Ile oun.
Kabiesi ti wa so pe iroyin eleje lasan ni baba yii n gbe Kiri nitori pe oun ki n se onijogbon rara bee lo so pe ki gbogbo awon eeyan mo pe Olorun lo yan oun gege bii oba ilu naa,bee lo so pe ki awon Oloye yii mase paro mo oun mo rara beeni ki won dekun lati maa so ohun ti ko dara nipa ipo oba ilu naa.
O tesiwaju pe,ko ye ki oun so ohunkohun nipa ipo ohun ti Balogun n so kiri nipa oun sugbon nitori oun n wa alaafia fun ilu oun atawon omo Bibi ilu lo je ki oun tete pe akiyesi awon eeyan si Oro naa,omowe oba naa wa so pe lenu igba die ti oun de Ori ipo oba ilu oun ,awon ayipada gidi ti de ba ohun gbogbo pelu bi eto ironilagbara ti oun se fawon odo ti mu iyato gidi ba aye opo awon odo ilu naa.
Oba Alade yii ti wa je ko di mimo pe,alaafia ilu lo je oun logun beeni oun yoo tesiwaju lati maa se ojuse oun gege bii oba alade ilu Orile Ilawo ati pe o da oun loju pe,pelu atileyin Olorun atawon eeyan daadaa ninu ilu oun,ki yoo si wahala mo nilu Orile Ilawo ati agbegbe re


No comments:
Post a Comment