Oludije sipo Gomina ipinle Eko labe Asia egbe oselu LP iyen Ogbeni Gbadebo Rhodes Vivour ti ki Dokita Alex Otti tipinle Abia ku oriire sipo Gomina ipinle naa labe Asia egbe oselu LP
Gbadebo soro ikini yii latenu agbenuso re nidi ise iroyin iyen,Judith Akatugba pe oriire nla ni egbe naa se ati pe ki Gomina tuntun fun ipinle Abia mase duro de igba ti yoo gba iwe ase ko to bere ise ribiribi ni sise
Dokita Alex Otti ti ibo to le ni 175,466 gbe e wole gege bii Gomina tuntun,nigbati egbe oselu PDP ni ibo 88,526 pere
Ogbeni Gbadebo ti wa so pe, idaniloju wa pe awon olugbe ipinle Abia yoo gbadun eto isejoba labe Asia egbe oselu LP
Bee lo n fi asiko yii ro awon olugbe ipinle Eko naa lati mo pe egbe oselu LP nikan lo le mu won de Ile ileri.

No comments:
Post a Comment