Leyin ipo Gomina ipinle Ogun, Oguntoyinbo Omo egbe NNPP Fe e dupo Aare ni 2027 - TOYIN ALARIYA ONLINE NEWS

Iroyin Yajoyajo

Adron Promo

Adron Promo
https://blog.adronhomes.com/promotional/

Sunday, July 16, 2023

Leyin ipo Gomina ipinle Ogun, Oguntoyinbo Omo egbe NNPP Fe e dupo Aare ni 2027


Odu ni Ambasado Ajadi Oguntoyinbo je ninu egbe oselu NNPP iyen egbe New Nigeria People's Party,oun ni oludije sipo Gomina ipinle naa ninu eto idibo to koja yii,bo tilejepe ipo naa ko ja mo o lowo latari idi Pataki kan ,to salaye fun Iko awon Akoroyin l'ede Yoruba iyen egbe League of Yoruba media practitioner lasiko ti won sabewo si ofiisi re ni Ibafo ipinle Ogun lose to koja,o wa so lojo naa pe, ijakule to waye  fun ti Gomina ti lo o,o ni ipo Aare Orile ede yii loun yoo du lodun 2027,nitori asoju awon Odo loun
O salaye lojo naa pe, Alaga egbe oselu Nnpp nipinle Ogun iyen Ogbeni Olaposi Sunday Oginni lo gbabode to si ta oun fun egbe oselu PDP ni idibo ku ose kan,o so pe Ogbeni yii lo gba owo lowo Oloye Ladi Adebutu to si kede pe egbe oselu Nnpp ti darapo mo egbe oselu PDP iyen egbe ti Ladi dupo Gomina labe e
O so pe, ibanuje lo maa n je fun oun nitori aarin awon ojelu ati onijekuje oloselu bii Oginni loun ti ba ara oun pelu igbese ojelu ti baba naa gbe lasiko ti idibo ku ose kan
Oguntoyinbo ti wa so pe,isakoso Aare Tinubu dara,ohun gbogbo n lo bo se ye ko lo,oloselu gidi ni baba naa bee loun nife lati sise ninu eto isejoba re nitori ife awon araalu wa lokan oun
Oguntoyinbo to tun je oludasile ileese Bullion Go-Neat Global Ltd to n se ohun mimu 'Coco Samba'fun imarale awon okunrin ti so pe ipese ise fawon Odo je oun logun pelu

No comments:

Post a Comment

Pages