Ogbeni Alamatu ko le pa idunnu re mora pelu bo se salabapade baba alaanu naa,o Fi idunnu re han fun ise takuntakun ti ileese Adrons Home and properties n se,pelu pipese eto Ile gbigbe Lona to rorun fawon Olugbe orile ede yii lapapo,bee lo dupe fun iranlowo ti ileese Adrons n se fawon agbofinro kaakiri awon ipinle wa
Aare Adetola naa wa dupe lowo ileese Olopaa Orile ede yii labe Oga agba,Egbetokun fun ifowosowopo won ati yiyan awon eeyan to kaju Osuwon sipo laarin osu die ti Omo bibi ipinle Ogun naa dori ipo bii Oga Olopaa.
Aare Adetola tun wa n Fi asiko yii so fawon onibara ileese Adrons pe,Ile gbigbe ti dirorun pelu ileese Adrons.
No comments:
Post a Comment