pọnmọpọnmọ ,ọga ni abuke,Oloye Oluṣẹgun Kẹhinde Aderẹmi Akinrẹmi tawọn eeyan mọ si Oloye Kanran ko ṣe e fọwọ rọ sẹyin laarin awọn agba oṣere,baba yii gba ikọ ẹgbẹ akọroyin l'ede yoruba lalejo lọsẹ to kọja nibẹ lo ti ṣalaye ọpọ nnkan nipa ara ẹ
Oloye Kanran sọ pe,ipinlẹ Eko ni wọn bi oun si ati pe ẹẹmẹfa ni iya oun bi ibeji,o sọ pe,ọmọ ilu Abẹokuta ati ile ifẹ ni oun ṣugbọn ipinlẹ Eko ni oun ti kawe,ile iwe St Paul pamari Idi oro Mushin,o tẹsiwaju lọ si Eko boys high School ,ati kings College leyin eyi lo lo si yunifasiti Eko lati lo ko nipa imọ aṣa ,níbẹ lo ti pade oloogbe Ayanfẹmi Oroniyi Phillips to je ọkọ iya Rainbow.
Oun ati ẹgbọn e,Ọgbẹni Yẹmì Rẹmi ni wọn jọ kawe ni ẹka ẹkọ ere tiata,oloye Kanran ṣalaye pe,oun fi iṣẹ tiata silẹ laarin kan nitori ilara,ati pe ọpọ awọn akẹẹgbẹ oun maa n pe oun ni onigberaga bẹẹ lo dẹ jẹ pe,ọpọ igba loun ti ṣiṣẹ ọfẹ fun pupọ ninu wọn o
Lasiko to n sọ nipa bi orukọ rẹ'Kanran ṣe waye,o sọ pe,lẹyin iku ọga oun iyẹn oloogbe Phillips ni ijoba ipinle Eko labe oloye Jakande so pe ki awon wa tun sinima ti baba Phillips n ya lo iyen leyin ti baba Oṣumare pajude,mo tun ranti pe ileeṣẹ redio tun jona lasiko naa,Segun Faloni,Leke Ajao Kokosari ni oloye sọ pe awọn jọ wa ninu Oṣumare theatre group nigba naa
Lẹyin ti wọn ri i pe oloye Kanran nikan lo le ko ipa ti oloogbe Oṣumare ko ti sinima naa si mi igboro titi lasiko naa lati igba yẹn ni oruko 'Kanran ti tayọ
Nipa ọjọ ibi oloye ti yoo waye lọjọ kẹrinlelogun oṣu kokanla,o ṣalaye pe ipele mẹta ni,ayẹyẹ ọjọ ibi,afihan fiimu to ṣèṣè gbe jade ati ifilọlẹ 'Kanran foundation ileewe ti wọn yoo ti maa kọ awọn eeyan ni bi a ṣe n ya sinima ati isaraloge atawọn ohun miiran
Oloye sọ pe,awọn osere bii Funkẹ Akindele,Mercy Aigbe,Kunle Afolayan mo riri oun nidi ise yii ti oun si mo idi tawon osere yii ki n se sise ofe nitori ko si ere kankan nidi sisise ofe fawon akeegbe oun
Oloye wa so pe,NUT Pavilion ni ikeja ni ayeye naa yoo ti waye ,aṣọ ati iwe ipe lawọn eeyan yoo fi wọle lọjọ naa
Lasiko ti oloye mẹnuba ọrọ Bayọwa Film lo ti sọ pe eeyan gidi ni ati pe esan n bẹ fun ohunkohun ti ẹda ba ṣe ninu aye,baba yii wa n bẹ awọn eeyan lati tako ahesọ ọrọ to n lọ nigboro pe aarin oun ati iya Abimbọ́la Ajayi ko gun rege,o sọ pe irọ ni o nitori abiamọ tootọ ni iya naa
No comments:
Post a Comment