Alẹ ọjọ kinni ọdun yii nibi ayẹyẹ ariya ọdun ti Oluaye fuji iyẹn Wasiu Ayinde ṣe ni ọkan ninu ọmọọṣe rẹ ti sọrọ buruku si oṣiṣẹ iwe iroyin Aarẹ Orilẹ ede yii kan lasiko ti olorin ẹmi nni iyẹn Olanrewaju Atoriṣe fẹ mu oniroyin naa wọlẹ sinu gbọgan ayẹyẹ
Noble tawọn kan tun mọ si king mabo lo sọ lọjọ pe oun korira Aarẹ fun idi eyi oun ko le gba oniroyin to n ṣiṣẹ nileeṣẹ Aarẹ laye lati wọle sibẹ,niṣe ni Atoriṣe kan n wo Noble lasiko to n wu iwa yii
Dipo ki Alaga ijọba ibilẹ isọlọ to tun jẹ manija Wasiu Ayinde ,ọnọrebu Ọlaṣoju jẹ kawọn oniroyin wọle ,awọn ọṣọmu ẹ lo n gba laye lẹyin tawọn iyẹn tawọn iyẹn ba ti pe e lori aago lẹnu ọna ṣugbọn ti Ọlaṣoju da awọn oniroyin duro sita ninu otutu

No comments:
Post a Comment