Oloye Ẹlẹlẹ to tun jẹ ọrẹ awọn mekunnu ti sọ pe,akoba lasan ni ija to ṣẹlẹ ni abule Agewe nijọba ibilẹ Owode nipinlẹ Ogun jẹ ati pe awọn ọta oun lo wa nidi ọrọ naa nitori lasiko tawọn ọdọ yi n ja oun ko si nitosi agbegbe naa ati pe nitori ayẹyẹ ọjọ ibi oun to n bọ lọjọ keje oṣu yii nibi tawọn ọdọ yoo ti gba fọọmu jambu ọfẹ bẹẹ lawọn arugbo ati opo yoo ti gbẹbun owo ati onjẹ
O sọ pe nibi ija naa ni ọgbẹni kan to n jẹ Rasaki Ọlatunji ti dawati doni in to si jẹ pe oun lo lewaju awọn ọdọ to n ja lọjọ naa
O ti wa sọ pe oun ko mọ ohunkohun nipa iṣẹlẹ naa to si jẹ pe ẹjọ yii ti wa nileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun ni Eleweeran

No comments:
Post a Comment