Ọjọ kọkandinlọgbọn si ọgbọn ọjọ oṣu kọkanla ọdun yii ni ileeṣẹ ADRONS yoo gbe idije ere idaraya lọlọkan o jọkan wọ ipinlẹ Ọyọ
Ẹlẹẹkeji iru ẹ re e ti yoo waye ni,sitediọọmu Lekan Salami ni Adamasingba,ere idaraya bii,ẹyin ori tabili(table tennis),ifosoke(long jump)ere sisa ati beebeelo ni yoo waye.
Won ti se iru eto yii nipinle Ogun ati Eko to si je pe igba keji re e ti won ma a gbe eto naa lo silu Ibadan.
Awon agba oje ninu ere idaraya ni orile ede wa nigba kan,Daniel Amokachi ati Mutiu Adepoju ni asoju ere idaraya ti ileese ADRONS sagbateru e nilu ibadan lodun yii
Opo ebun lawon to ba gbegba oroke yoo je ti opo yoo si fi idunnu pada si ile won.
Lasiko ti oludasile ileese naa n ba awon akoroyin soro,Aare Emmanuelking so pe,lati le je kawon onibara ileese re mo riri ere idaraya pe o n fun ni lokun bee lo n je ki ara ji pepe lo mu ileese naa gbe eto yii kale,ti o si je pe gbogbo ere idaraya to wa lawon eeyan yoo se lojo naa.
Akori eto ti odun yii ni'Wa pipe lati gbooro ''o so siwaju pe,o dara ki eda eeyan ni ipinnu lati di eeyan pataki lawujo,beeni imele sise ko le gbe eeyan de ibi giga
Boya iwo fe mo si i nipa eto yii tabi o fe ra ile nileese ADRONS,pe ogbeni Abiodun sori 08138432335
No comments:
Post a Comment