Lati gbogun ti aarun 'jẹjẹrẹ ọmu'ileese Adrons gbe eto ayewo iwosan ọmu ọfẹ kalẹ - TOYIN ALARIYA ONLINE NEWS

Iroyin Yajoyajo

ILEYA TI DE

ILEYA TI DE
ILEYA TI DE

Thursday, October 31, 2024

Lati gbogun ti aarun 'jẹjẹrẹ ọmu'ileese Adrons gbe eto ayewo iwosan ọmu ọfẹ kalẹ






Toyin Agbọlade
Ileeṣẹ ADRON pẹlu ajọṣepọ 'Pink clinic ti gbe eto kan to ma n waye lọdọọdun kalẹ fawọn obinrin to n koju aarun jẹjẹrẹ ọmu kaakiri orilẹ ede yii.
Ẹlẹẹkẹrin iru ẹ ree to waye ni olu ileeṣẹ ọfiisi ADRON to wa ni Ọmọle nipinlẹ Eko nibiti Olori Aderonkẹ Emmanuelking ti siwaju awon obinrin lati rin kaakiri pelu ipolongo ona abayo si aarun jejere omu
Olori Aderonke to je iyawo oludasile ileese Adron so lojo naa pe,akikanju lawon obinrin ti aarun naa n baja bee lo dupe lowo molebi iru awon eeyan bee fun aduroti won,o gbe osuba kare lai fawon to ti ja ajaye bee lo sadura fawon ti emi won ba ipenija aarun jejere omu lo.
O wa so lojo naa pe,Adron home CRS ati ajosepo pink clinic ti setan lati sayewo ofe fawon to nipenija aarun naa.
Eto to da lori,ayewo omu ofe,idanileko lori aarun jejere omu,ona lati gbogun ti gbogbo aisan lago ara ati fifun opo obinrin loogun ofe
Oga ile iwosan Pink clinic,dokita Linda Keku naa gba awon obinrin nimoran lojo naa lati maa wa nimototo,ki won si maa lo si ile iwosan ti won ba sakiyesi ohunkohun to yato lago ara won.Olori Emmanuelking ti wa seleri atileyin pe,ileese Adron yoo tesiwaju pelu eto to ma n waye lodoodun nitori alaafia awon obinrin lati bo lowo aarun asekupani yii lo je oun logun

No comments:

Post a Comment

Pages