Ọsẹ onibara ọdun yii,ileeṣẹ ADRONS ṣeleri igba ọtun fawọn onibara ẹ - TOYIN ALARIYA ONLINE NEWS

Iroyin Yajoyajo

ILEYA TI DE

ILEYA TI DE
ILEYA TI DE

Tuesday, October 15, 2024

Ọsẹ onibara ọdun yii,ileeṣẹ ADRONS ṣeleri igba ọtun fawọn onibara ẹ




Toyin Agbọlade
Ọjọ monde iyẹn ọjọ aje ọjọ keje si ọjọ kọkanla oṣu kẹwa yii nileeṣẹ to dangajia nidi iṣẹ ilẹ ati ile tita lọna irọrun,ADRONS tun seleri otun fawon onibara won pe,nipa rira ile nileese yii ko si aya jija kankan .
Eto ti akori re jẹ'itayọ ati idayatọ'naa sọ nipa bi ileeṣẹ yii yoo ṣe tubọ maa ṣe ohun ti yoo ma mu inu awọn onibara dun nigba gbogbo.
Beeni ileese ADRON tun moriri awon osise re to se daadaa,eto ilera ofe nipa sisayewo ilera,idanileko bi a se n toju ago ara,anfaani ilera pipe fawon osise ati onibara,iwulo ife aisetan laarin olutaja ati oluraja.
Olori eka osise ileese naa,Arabinrin Hastrup Aminat Olaniyan tun soro lori bii awon osise se le gba awon onibara nimoran lati le mo anfaani ati iwulo ti didi lanloodu ara won se le bu iyi kun won lawujo
O salaye ojuse osise kookan pelu,beeni oludasile ileese Adrons,Aare Emmanuelking Adetola naa so anfaani to wa ninu fifi onibara se'akọkọ nileeṣẹ fawọn oṣiṣẹ rẹ,o sọ pe,titẹ onibara lọrun nikan nidaniloju pe,ileeṣẹ kogojari to si jẹ pe ojuṣe ati aigbọdọ maṣe leyi jẹ nileeṣẹ ADRONS nitori tite onibara lorun lo je ki ileese naa da yato laarin awon akegbee e
O salaye siwaju si i pe,lati le je ki awon osise mo pe,onibara lo gbodo je akoko beeni biba onibara soro tutu lo le mu inu won dun lati ba won dowopo .
Boya iwo fe mo si i nipa ileese Adrons,tete maa lo si eyikeyi ofiisi won to ba sunmo odo re

No comments:

Post a Comment

Pages