Toyin Agbolade
Loooto ni ariwo'Anobi merin nidi ise orin Fuji to gba igboro kan l'enu ojo meta yii ti lo sile iyen leyin ti Alhaji Saheed Osupa so pe,Anobi merin pere lo wa ninu awon to n ko orin Fuji.
Osupa so pe,Alaaji Wasiu Alabi Pasuma,oun Osupa, Alaaji Abass Akande Obesere ati Mr Fuji funra e iyen oloogbe Sikiru Ayinde Barrister nikan ni Anobi ninu ise Fuji
Sugbon ti Osupa gbagbe lati daruko Alaaji Sulaimon Adio Atawewe,eni tawon ololufe e mo si,Wewe Anobi.
Ohun to je ki Atawewe je Anobi akoko nidi ise orin Fuji ni pe,inagije re 'Wewe Anobi gan an lo ti n je lati opo odun seyin Koda ki o to o maa je awon oruko bii,Mr Spirit,Akile Fuji,Mr Ronaldo,Etu Fuji ati baba oloye.
Ohun to je ki 'Wewe Anobi da duro ni ona toun fi n ko orin Fuji tire lona to mu ogbon,imo ,ati oye dani to si je pe bi onigbagbo omoleyin Jesu se le ri ogbon ko ninu orin e lawon elesin isilaamu naa le bu omi imo mu nibe ti eyi ko si yo awon elesin kan abalaye sile.
Yoruba to dun un gbo s'eti ni Wewe Anobi tun maa fi n ko orin re ti oye yoo si tete ye opo eeyah to ba n gbo orin naa.
Ohun to daju saka ni pe, Atawewe ni Anobi akoko nidi ise orin Fuji nitori oun ni Anobi koko wa ninu oruko re laarin awon onifuji asiko yii
No comments:
Post a Comment