Ileese ADRONS se bebe nibi ipade awon onisowo ile to waye nipinle Oyo - TOYIN ALARIYA ONLINE NEWS

Iroyin Yajoyajo

Lemon Friday

Lemon Friday
Lemon Friday

Saturday, December 7, 2024

Ileese ADRONS se bebe nibi ipade awon onisowo ile to waye nipinle Oyo


Oludasile please ADRONS,Aare Adetola Emmanuelking ti soro nibi eto ti awon onisowo ile tita ati rira iyen egbe REDAN se nipinle Oyo lenu ojo meta yii pe,Inu oun dun lati wa nibi ipade naa,to si so pe,ifowosowopo laarin egbe lo le tete mu ki opo awon eeyan di onile lori nipinle naa.
Eto ti olubadamoran nipa Oro ile gbigbe ati idagbasoke si gomina Seyi Makinde,iyen Onorebu Akinsete Olakunle gbe kale lopo awon eeyan jankan jankan nidi ise ile,Oro aje ati eto ile gbigbe ti wa ni kale ti won si jiroro lori bii idagbasoke yoo se ba eto ile gbigbe 
Igbakeji gomina ipinle Oyo,Agbejoro Bayo Lawal naa wa nibi ipade ti akole re je'ona imugbooro , idagbasoke ati olaju si ise ile gbigbe lona irorun 'lasiko ti oludasile please ADRONS n ba awon to wa nibe soro lo ti so pe,Inu oun dun pe ileese ADRONS wa lara awon ileese to n wa itesiwaju fun ona lati je ki ile gbigbe di irorun fopo eeyan nipinle Oyo.
Aare Adetola wa so pe,oun to je dandan fun egbe yii ni pe ki opo awon to ti so ireti nu nipa ile Kiko ji giiri lati mo pe,awon le di onile lori lona irorun,eyi si le waye nipa ifowosowopo laarin egbe REDAN.
O tesiwaju pe,ileese ADRONS ni ile ni ,Moscow park and garden Moniya lojuna Is eyin ati West Park and garden Aiyegun Oleyo atawon ibomi in.
Igbakeji gomina ipinle Oyo Agbejoro Bayo Lawal gbe osupa kare lai fun ileese ADRONS bee lo si so pe ohun iwuri lo je bi ileese naa se n wa itesiwaju egbe REDAN.

No comments:

Post a Comment

Pages