Esi Ayẹwo DNA! Barryshowkey wọ studio l'Amẹrika,Rẹkọọdu nla lo gbe jade o - TOYIN ALARIYA ONLINE NEWS

Iroyin Yajoyajo

Adron Promo

Adron Promo
https://blog.adronhomes.com/promotional/

Sunday, July 19, 2026

Esi Ayẹwo DNA! Barryshowkey wọ studio l'Amẹrika,Rẹkọọdu nla lo gbe jade o



Gbogbo ise lo ti pari lori rekoodu tuntun ti gbajumo olorin fuji nni, Adewale Akanji Barryshowkey fee gbe jade. 

Rekoodu tuntun ohun to pe ni 'DNA' test lokunrin omo Oloogbe Sikiru Ayinde Barrister to fi orilẹ-ede Amerika segbube naa fee fi tu asiri nipa oro kan tawon eeyan kan n gbe kiri pe Barusaati ko lo bi i. Awo ohun ti won po po lorile-ede Amerika ati Nàìjíríà l'osere nla ohun fi salaye fun gbogbo aye lori ibeere wọn, pàápàá awọn mọlẹbi kan ti ọrọ ẹ ṣokunkun sí, atawon kan ti won ni ko lo se DNA, iyen ayẹwo ẹjẹ ti yóò fìdí è múlẹ pe lóòótọ́ omo Sikiru Ayinde Barrister loun naa n se ní tododo.

Barryshowkey, Adéwálé Àkànjí ti da wọn lohun o, ninu rekoodu to pe ni DNA Result, gbogbo ibeere awọn to fẹ mo bo se je gan an laarin awọn ọmọ Agbajelola lo ko ni sinu rekoodu oniseju mewaa pere to gbe jade, eyi ti yóò gbà ori gbogbo ẹrọ ayelujara kan, bíi audiomac, Spotify ati bẹẹ lo ti awọn eeyan ti le gbo ojúlówó orin gidi.

No comments:

Post a Comment

Pages