Iyaafin Toyin Kolade di Iyalaje Oodua - TOYIN ALARIYA ONLINE NEWS

Iroyin Yajoyajo

ILEYA TI DE

ILEYA TI DE
ILEYA TI DE

Wednesday, July 21, 2021

Iyaafin Toyin Kolade di Iyalaje Oodua

Ilu ile-ife mi titi lojo ketadinlogun osu yii nibi ti Ooni Ile ife iyen oba Babatunde Adeyeye Ojaja 1 ti ja ewe Oye le iyaafin Toyin Kolade to je oludari ileese Fisolak ti ofiisi won wa nilu Eko Lori.
Oye iyalaje oodua ni Oba Adeyeye fi iyaafin Toyin je nitori ipa tibitibi ti obinrin bii okunrin yii n ko Nile Oodua kaakiri,awon eeyan Pataki lo peju sibi eto jija ewe Oye le iyaafin Toyin lori,awon oba alaye bii Oba Folarin Ogunsanwo iyen Alara ti ilu Ilara,Alapomu iyen oba Kayode naa wa nikale lojo naa.
Iyalaje Oodua tuntun naa wa seleri lati mu iseese ni okukudun,ti o si tun so pe oun setan lati se awon ohun ti gbogbo omo kaaro o jiire nreti latodo oun gege bii iyalaje oodua.Olori fun gbogbo awon onifuji iyen Alaaji Wasiu Ayinde lo dalu bole lati fi da awon eeyan to wa nibi ayeye naa laraya.


No comments:

Post a Comment

Pages