Mo maa n ko oriire ran awon onibara mi nitemi ni---Ogbeni Arems - TOYIN ALARIYA ONLINE NEWS

Iroyin Yajoyajo

ILEYA TI DE

ILEYA TI DE
ILEYA TI DE

Saturday, February 26, 2022

Mo maa n ko oriire ran awon onibara mi nitemi ni---Ogbeni Arems

Lose to koja ni Ogbeni Aremu Wasiu Adeniyi to je alase ati oludari Arems ati 1st Eleven 9ja to n gbe awon olorin takasufe ati olorin Fuji kan si ileese Tojubole to si je ko di mimo pe oun gege bii oludari ileese Arems maa n ko oriire ba awon olorin to n jade labe ileese oun ni.
Ogbeni Aremu tun so pe opo awon olorin ni ko mo ohun ti won n fe latodo awon to n dari won,to si je pe ibeere akoko ti oun maa n beere lowo olorin to ba wa sodo oun niyii.
O salaye pe ipile to dara se Pataki,igbora eni ye se Koko,ifowosowopo je aigbodo ma ni beeni titete sawari irufe talenti ti olorin naa ni se Pataki.O tun so pe ifarada ati owo lati fi seto awon ohun ti yoo je ki Orin ti oun ba gbe jade tete ta lori igba je ohun aigbodo ma ni beeni bibara eni soro loore koore ati imototo je Pataki laarin oun atawon onibaara oun,o wa so pe ti asoye ba ti wa laarin awon ko si wahala rara.


No comments:

Post a Comment

Pages