Ohun ti e ko mo nipa Oluaye Fuji re-e - TOYIN ALARIYA ONLINE NEWS

Iroyin Yajoyajo

Adron Promo

Adron Promo
https://blog.adronhomes.com/promotional/

Thursday, August 18, 2022

Ohun ti e ko mo nipa Oluaye Fuji re-e

Ojo keta osu keta odun 1957 ni won bi Oluaye fun gbogbo awon onifuji iyen Alaaji Wasiu Ayinde Marshal,omo Bibi ilu Ijebu ode ni sugbon iya re wa lati ilupeju nipinle Ondo.
Wasiu kawe gidi bee lo bere ise Orin latigba to ti wa ni omo odun mesan,adugbo Agarawu nipinle Eko ni won bi i si,odun 2001 lo di Oluomo Eko labe oba Eko igba naa iyen Oloogbe Oyekan keji.
Osu kinni odun 2020 lo di Mayegun Ile Yoruba labe Alaafin ana nilu Oyo iyen iku baba Yeye Oloogbe Oba Adeyemi,omo mejidinlogoji ni Oluaye bi to si n so pe oun nife lati bi ibeji si i.
Odun 1979 o gbe awo Orin solo jade to pe akole re ni'Abode Meka,odun 1984 o gbe 'Talazo 84 jade,o ti gba Ami eye lorisirisi bee lo ti rinrin ajo kaakiri Orile ede lagbaye.
Ayeye aadota odun to ti n korin yoo waye nipinle Eko losu yii,Mayegun Ile Yoruba maa Jaye Ori e lo,omo Ojusagbola Ogoji nijebu Ode,Olorun wa leyin re jare.


No comments:

Post a Comment

Pages