Ko si Oro oselu ninu eto ikaniyan odun 2023 yii---Ajo Eleto Ikaniyan NPC - TOYIN ALARIYA ONLINE NEWS

Iroyin Yajoyajo

Lemon Friday

Lemon Friday
Lemon Friday

Sunday, March 19, 2023

Ko si Oro oselu ninu eto ikaniyan odun 2023 yii---Ajo Eleto Ikaniyan NPC

Ajo Eleto Ikaniyan odun yii ti so pe,Ilana ati eto ikaniyan to fe waye Lorile ede Naijiria lodun 2023 ti a wa ninu e yii ko ni ohunkohun se pelu pelu Oro oselu rara,Ajo naa salaye gbogbo eto lo ti pari lati ri i pe ohun gbogbo lo wa bo se ye ko wa
Komisona fun Oro eto ikaniyan NpC nipinle Ogun iyen onarebu Arabinrin Seyi Aderinokun lo salaye awon Oro wonyii nibi idanileko olojo kan to waye nilu Abeokuta nipinle Ogun,tawon oniroyin to laami laaka nidi ise iroyin si wa nibe lojo toside ose to koja, Arabinrin yii salaye pe,eto ikaniyan yii ko ni ohunkohun se pelu Oro eleyameya rara.O tesiwaju pe,eto ikaniyan yii wa ni ibamu pelu ofin to ba Oro Orile ede yii mu
Ogbeni Olusola Adeleye lo soju Arabinrin Aderinokun lojo naa ti Adeleye si so pe,ero igbalode ayarabiasa ti yoo je ki ise ikaniyan tete ya ti wa nile
Otunba Lanre Anifowose to je oga agba sugbon to ti fehinti nileese Ajo NPC naa soro lojo naa pe,gbogbo ibudo  Sambisa tawon agbebon ti so di ibudo lawon yoo ka ninu eto ikaniyan ti yoo waye ninu osu karun-un odun yii
Anifowose so pe,awon ti lo sibudo yii lati ba awon to wa nibe soro,Ogbeni Folami naa ki Oro Anifowose leyin gege bii okan ninu awon alakoso nileese naa pe,loooto lo je pe odun mewa mewa lo ye ki eto idibo maa waye sugbon ti nnkan pada yiwo sugbon tawon maa je ki todun yii waye lona irorun
Ogbeni Alayaki naa so pe,awon awako, akoroyin atawon molebi won lawon yoo ka nigbati alakoso telifisan ijoba apapo Arabinrin Funmi Wakama wa ro awon akoroyin lati sise papo pelu awon Ajo Eleto Ikaniyan nipa gbigbe iroyin otito ninu eto ikaniyan odun yii bee lo so pe Ajo naa setan lati fun awon oniroyin ni ohunkohun ti won ba n fe lati le gbe iroyin otiito,nitori Ajo naa ko fe iroyin eleje tabi iroyin ofege rara.



No comments:

Post a Comment

Pages