Gege bi iroyin to te wa lowo se so pe,Ogbeni Musibau Olawale Babalola eniti awon ti e mo si Wale Bouncer to je gbajumo puromota ni Orile ede America ti gbe Ogbeni Okikiola Habeeb Badmus iyen Portable Zazu to je olorin takasufe lo sile ejo bayii
A gbo pe,Wale Bouncer fe gbe Portable lo si Orile ede America ti , Wale Bouncer si ti na owo to le ni milioonu mejo Lori awon eto naa sugbon ti a gbo pe portable ko fesi gidi fawon Oyinbo alawo funfun to n beere Oro lowo e lasiko idanwo ranpe ni Ofiisi awon Oyinbo America (Embassy)
A gbo pe ,awon Oyinbo ko fun Portable ni fisa lati so Orile ede America,nitori wonran-wonran to n se nibe lojo naa,a fi bi a se gbo pe Portable fariga pe,oun ko setan lati sanwo kankan fun Ogbeni Bouncer
Ni bayii, Ogbeni Bouncer to tun ni ileese Fathia promotion ni Orile ede America ti gbe Portable lo sile ejo pe a fi ko San owo ti oun ti na le e lori,a gbo pe Portable ti san milioonu meji ninu milioonu mejo sugbon ti who naa ti wa Nile ejo,Loya awon mejeeji si ti setan lati gbeja onibara won bayii

No comments:
Post a Comment