Wolii Sam Olu Alo to je Oludasile ijo Christ Apostolic Church,Grace Of Mercy Prayer Mountain International ti so lose to koja lasiko to n ba awon Akoroyin soro pe,were iyen alaaganna ni Olorun lo lati jise foun pe,ise Oluwa ni ise ti Olorun Fe ki oun se Lori Ile alaaye
Baba Adamimogo gege bii oruko ogbontarigi iranse Olorun Alaaye naa so pe,opo odun loun fi ko ise birikila iyen awon to n ko Ile,sugbon lojo kan ni were kan jise foun pe'Olorun n pe o,o n ko eti ikun aanu re n se mi,yoo dara ki o tete gboran si Olorun lenu ki ojo to o lo.
Wolii Sam wa so pe,ohun to je ki Oro were yii ya oun lenu ni pe,ojo to ye ki oun gba iyonda kuro lodo Oga re to ko o ni ise birikila gan an ni Oga re yii le e Danu,o salaye pe, leyin ti were jise foun tan ,loun la ala ri Apositeli Joseph Ayo Babalola,ti baba naa si so foun loju ala pe, Olorun Fe lo oun lati tu ide aye opo eeyan ati lati jere okan fun Kristi Olugbala
Ni bayii,iranse Olorun Alaaye yii ti n gbaradi lati gbalejo nibi ipago kan ti yoo waye ninu osu kejo yii nibi ti won ti n reti opo eeyan atawon iranse Olorun nibi ipade ohun.
Ipago re ti won n pe ni,Jesus City Camp to wa l'Eko ni ipago adura naa yoo ti waye nibe ni Jesu yoo ti tu opo awon to wa ninu ide sile.

No comments:
Post a Comment