Egbe Akoroyin nipa awon gbajumo lawujo l'ede oyinbo se bebe nipinle Eko - TOYIN ALARIYA ONLINE NEWS

Iroyin Yajoyajo

Lemon Friday

Lemon Friday
Lemon Friday

Friday, September 1, 2023

Egbe Akoroyin nipa awon gbajumo lawujo l'ede oyinbo se bebe nipinle Eko

Ojo toside iyen ojo ojobo to koja lo yii ni Egbe Akoroyin nipa awon gbajumo lawujo l'ede oyinbo gbe eto fifo ilu mo tonitoni fun ti odun yii wa sigboro Eko.Ikeja ni eto naa ti bere nibi ti arewa oseretiata obinrin nni iyen ,Foluke Daramola Salako ati Alaaji Atawewe to je gbajumo olorin Fuji ti kopa ninu eto naa
Alaaji Atawewe so pe idi ti oun Fi darapo mo eto imototo ilu Eko ati agbegbe re ni pe,igboro ni pupo ninu awon onifuji ti n ri owo ,to tumo si pe o Dara lati tun ibi tawon ti n rowo se, Foluke Daramola Salako naa so pe,eeyan ko le se ko ma rin nigboro laarin ojo meji,idi eyi lo se ye ki eeyan tun ibi to n Rin si to tun ti n ri taje se se ati pe imototo lo le segun gbogbo aarun
Ajo Lawma iyen Ajo to n ri si imototo nipinle Eko naa ba won da si eto yii pelu bi won se gbe Awon oko ikodoti si wa lati wa ko awon idoti ti Iko yii ko Jo lasiko eto ifolu Eko mo tonitoni naa
Aare egbe iyen ogbontarigi Akoroyin l'ede oyinbo to tun je Oludasile Ileese Islander magazine iyen Alaaji Olanrewaju Mohammed wa dupe lowo awon Omo egbe atawon to duro lati je ki eto ifolu Eko mo todun yii yori si daadaa bee lo seleri lati tubo je ki ipinle Eko ati agbegbe re wa ni imototo

No comments:

Post a Comment

Pages