Oloye Ọlabode Ibiyinka George la n wi,ọmọ bibi ipinlẹ Eko ni baba agba ninu oṣelu Naijiria to ni oun yoo filu silẹ ti Aarẹ Tinubu ba di Aarẹ Orile ede yii la n sọrọ rẹ,baba yii ti wa sọ oju abẹ niko fun ikọ ẹgbẹ Akọroyin l'ede Yoruba iyẹn League of Yoruba Media practitioners lasiko to gba wa lalejo lọjọ iṣẹgun ọsẹ to kọja
Baba naa sọ pe,a ko fẹran ara wa gẹgẹ bii iran Yoruba ati pe nnkan buruku meji to n da wa laamu ni esin ati ẹlẹyamẹya ,o sọ pe inu lo yẹ ki ẹsin wa,ẹsín sọ pe ,ki a ma ṣe ika fun ọmọnikeji wa bẹẹ lo jẹ pe,ẹsin mẹta la ni ni orilẹ ede wa,ẹsin kiristẹẹni,ẹsin musulumi ati ẹsin yeeparipa iyẹn ẹsin abalaye ,ko si idile ti ki n ṣe ọkan ninu awọn ẹsin yii
Kristẹẹni ni wa ni idile wa,ẹgbọn mi fẹ musulumi,aburo mi fẹ musulumi to tun pada di kristẹẹni,ẹtan ti pọ ju ni orilẹ ede yii,iwe Ofin ti Aarẹ ana,Oloye Jonathan ṣe atunto rẹ ni ki a lọ ọ gbe,ki a tẹle e pẹlu.Baba yii tun sọ lọjọ naa pe,agbara ti wọn gbe fun Olori oko ti pọju,o sọ pe,ipinlẹ Eko gan an tobi ju fun ẹnikan ki a ma tun wa sọ odindin Orilẹ ede yii,awa ko gbogbo ẹ o di Abuja,eeyan kan wa joko ti i ,o ti pọju.
Aarẹ Tinubu yan awọn Yoruba si ipo ,lasiko Aarẹ Ana iyẹn Buhari ohun to ṣẹlẹ naa ni yẹn,ti emi naa ba de ipo yii maa yan awọn temi,ẹ jọwọ ṣe bi ilu ṣe maa to ni yii?
Buhari tan wa pe,oun ti ra maṣiini tuntun fun eto idibo lasiko to n ṣejọba,inu wa dun koda a ṣe ajọyọ ninu ile mi nibi ṣugbọn nigba ti asiko idibo de,wọn sọ pe,awọn maṣiini naa ti bajẹ
Ọna abayọ si iṣoro orilẹ ede yii ni pe ka ba awọn eeyan sọ otitọ ọrọ ẹ ma pa irọ fawọn araalu mọ,mi o sọ pe ki wọn tu ilu ka o,iya to n jẹ awọn araalu ti pọ ju,owo dọla ti ba Naira wa jẹ bẹẹni a ko na owo dọla,kilo wa fa inira fun wa?
Ẹgbẹ akoroyin wa beere idi ti baba ko ṣe fi orile ede yii silẹ lẹyin ti Aarẹ Tinubu de ipo,baba sọ pe,ko si ẹni to le da mi duro ti mo ba fẹ kuro ni orile ede yii,mo ti jade mo dẹ tun wọle pada,lasiko ti idibo n bọ wọn ran awọn eeyan wa bẹ mi pe awọn mọ pe awọn ti ṣe ika fun mi ṣugbọn ki n ni suuru,emi ti mo ti joko sinu yaara olori oko ni Villa ri,emi naa ni won tun ran lo si kirikiri lati lo ri idakeji aye ti mo si dupe pe,opo awon ti akoba gbe de kirikiri ni won gba itusile nipase mi,ohun ti Olorun fe ki n lo se nibe niyen
Asiko kan wa tawon agbaagba nipinle Eko so pe ki n lo ki olori oko tuntun ni Abuja ṣugbọn mo sọ fun wọn pe ko ṣeeṣe nitori aṣoju ẹgbẹ ni mi,kini ki n sọ fun ẹgbẹ pe mo n wa kiri?
Nipa egbe oselu pdp nipinle Eko,Oloye Bode ṣalaye pe,iwa abosi ati ọdale ti ogbẹni Jandour wu lo mu u padanu ibo naa pẹlu bo ṣe fariga pe oun ko fẹ fi Gbadebo Vivour se igbakeji to si lo mu obinrin kan wa lati ikorodu,ka ni pe ,Vivour ni Jandour fi se igbakeji ni idaniloju wa pe,egbe oselu Pdp ni yoo wọle ninu eto idibo to kọja
Ju gbogbo ẹ lọ,oloye Bọde George ti sọ pe,otito lo le mu orilẹ ede yii de ilẹ ilẹri ati pe kawọn to wa loke ranti awọn mẹkunnu nitori iya to n jẹ awọn ara ilu ko kere rara
No comments:
Post a Comment