Ijọ Genesis Global ti pe gbogbo awọn ọmọlẹyin Jesu sibi eto aṣalẹ orin iyin wọn ọlọdọọdun,ti aṣalẹ orin iyin tọdun yii maa waye ni ọjọ kẹẹdogun oṣu kejila ọdun yii nile ijọsin wọn to wa ni adugbo Duro Ishọla,Egbado Alakuko ipinlẹ Ogun
Awọn olorin ẹmi ọjọ naa ni Moses Harmony,Bidemi Ọlaọba,Bukọla Ittah,Moji Daramọla,Apekeọla,Dare Oxygen,Oluwasegunfunmi02,Engo,ati onkorin Rain.
Oluṣọ Ọladele Ogundipẹ to jẹ oludasilẹ ijọ Genesis Global lasiko to n ba wa sọrọ sọ pe,ogun n di ṣiṣe nipasẹ orin iyin,bẹẹni agan n di ọlọmọ ati pe agbara Jesu to ṣẹgun aye ọpọ eeyan ninu bibeli ṣi wa sibẹ lati ja ide ati tu ide
Oluṣọ Ọladele tun wa bẹ awọn ijọba wa lati dena ija ẹsin lorilẹ ede yii

No comments:
Post a Comment