Ti a ba n sọrọ nipa iranṣẹ Ọlọrun alaaye,tawọn iṣẹ aami ati iṣẹ iyanu n ti ọwọ rẹ ṣe lagbaye lasiko yii,ọkan pataki ni wolii Samuel Ojo Ọmoloju Jesu,Authority lọpọ mọ wolii Sam Ojo si pẹlu.Oun ni oludasilẹ ijọ Freedom Apostolic Revival Ministry(FARIM)ati oludari ori oke to wa ni Aṣejirẹ nipinlẹ Ọyọ.
Pasitọ Ọmọloju Jesu ti wa sọ lọsẹ to kọja nibi eto ṣiṣi ileeṣẹ redio rẹ tuntun iyẹn Melody 107.7fm nipinlẹ Eko pe,ọlẹ afajo ni iranṣẹ Ọlọrun ti ko ba wa iṣẹ miiran ṣe kun iṣẹ Oluwa to ba n ṣe.Authority sọ pe,iranṣẹ Ọlọrun to gbẹkẹle owo ijọ ati idamẹwa jẹ ọlẹ ati onimẹlẹ nitori Ọlọrun gan an korira ọlẹ eeyan.
Baba Ori oke ogo ṣalaye fawọn oniroyin lọjọ naa pe,oun ko gbokanle owo ijọ rara nitori ẹ lawọn ọmọ ijọ oun ṣe n janfaani iwe ẹkọ ọfẹ,lilọ kawe nilu oyinbo,riran awon opo lọwọ bẹẹ lawọn ọmọ alailobi naa n ri ẹbun iṣẹ ọwọ kikọ jẹ nile ijọsin oun,o sọ pe ti Ọlọrun ba ti fun ẹda eeyan ni owo ati ile gbigbe ,riran awọn alaini lọwọ lo tu ku fun iru ẹda bẹẹ agaga ki aṣiri ẹni naa bo ko tun wa ni ọkọ ayọkẹlẹ,o dara kiru ẹni bẹẹ mọ pe inu Ọlọrun yoo dun ti oun ba le maa ran alaini ati opo lọwọ.
Authority sọ pe,oun ni iṣẹ mi-in yatọ si iṣẹ iranṣẹ toun n ṣe,oun n ta goolu,aṣọ bẹẹ loun jẹ oniṣowo ilẹ ati iletita,o ṣalaye pe ọdun mẹrin sẹyin loun ṣeṣe di onile lori nitori asiko Ọlọrun lo ju ninu irin ajọ eda eeyan ninu aye
Nigba to n sọrọ nipa redio rẹ to ṣẹṣẹ ṣi sipinlẹ Eko,o sọ pe ki n ṣe ọrọ ṣọọsi nikan ni wọn n sọ nileeṣẹ redio Melody f.m o,gbogbo eto to le kọ eeyan lọgbọn ni wọn n ṣe nibẹ,bẹẹni ede mẹtẹẹta ,hausa,ibo ati yoruba ni wọn n ṣe awọn eto lori redio naa,o ti wa sọ pe,eto ti n lọ lọwọ nipa ṣiṣi redio si ilu ibafo,Abeokuta nipinlẹ Ogun ati Ibadan nipinlẹ Ọyọ pẹlu,o ṣalayẹ pe oun mọ riri eto ibanisọrọ gẹgẹ bii ọmọ bibi ilu Ibadan.

No comments:
Post a Comment