Ẹgbẹ apoogun ti f'ẹsun ibanilorukọ jẹ kan Abati,Chukwunedu ,bẹẹni ileeṣẹ BULLION GO-NEAT n beere fun idajọ ododo - TOYIN ALARIYA ONLINE NEWS

Iroyin Yajoyajo

Adron Promo

Adron Promo
https://blog.adronhomes.com/promotional/

Monday, February 19, 2024

Ẹgbẹ apoogun ti f'ẹsun ibanilorukọ jẹ kan Abati,Chukwunedu ,bẹẹni ileeṣẹ BULLION GO-NEAT n beere fun idajọ ododo


Ileeṣẹ BULLION-GO-NEAT iyẹn ileeṣẹ to n ṣe oogun amara ji pepe to n jẹ COCO SAMBA, ti sọ pe ,irọ nla ni iroyin to n lọ nigboro pe oogun olomi to wa fun imularale iyẹn Coco samba ko dara fun ilera awon eeyan.Oludasilẹ ileeṣẹ naa Ambassador Olufẹmi Ajadi Oguntoyinbo lasiko to n sọrọ lo ti sọ pe,ohun iyalẹnu lo jẹ nigbati oun ri iroyin ẹlẹjẹ naa lori ẹrọ ayelujara pe,coco samba kun fun awon eroja to le sakoba fun ilera ẹda ati pe orilẹ ede Germany ni won ti ri i pe,coco samba ko dara fun ilera awon eeyan
Ogbontarigi oloṣelu naa sọ pe,ọ jẹ ohun to ri bakan lọkan oun pe pẹlu bi ọlaju ṣe ti gbode yii,awọn oniroyin ori ẹrọ ayelujara kan ṣi le maa gbe iroyin ẹlẹjẹ lai kan si ileeṣẹ ti wọn fẹsun eke kan naa,o ṣalaye pe awọn oniroyin yii ko ri ootọ gba mu bẹẹni ko si ẹri to daju pe loootọ ni ajọ NAFDaC iyen ajọ to n mojuto ounjẹ jijẹ,ohun mimu ati ohunkohun to ni i ṣe pẹlu ilera awọn olugbe orileede yii ko ri ẹri pe loootọ ni coco samba ko dara fun ilera awon eeyan.
Agbejọro ileeṣẹ BULLION-Go-Neat ,Isaac Izunya ti wa so pe ko si iwadi to fidi ẹ mulẹ pe,coco samba ko dara nitori ko si enikeni to mu leta wa beeni iwadi to yanranti loun ṣe lọdọ ajọ Nafdac ti ko si enikẹni to sọrọ coco samba laida ,o wa so pe,ileeṣẹ ọlọpaa to wa ni Adeniji Adele,ọga ọlọpaa nipinlẹ Eko,ileeṣẹ ologun SARS,ileeṣẹ ọlọpaa to wa ni Alagbọn ati ọgbẹni Abati pelu arabinrin Chioma Chukwunendu gbodo wa sọrọ lori ẹsun ibanilorukọ jẹ ti wọn fi kan onibara oun iyẹn ileeṣè coco samba ti ambassador Oguntoyinbo naa si ti so pe awon onise ibi ni won sanwo fawon oniroyin ayelujara lati fenu abukun kan ileeṣẹ oun nitori gbogbo ohun to yẹ lati ṣe fun orlẹede oun bii owo ori sisan,ipese iṣẹ fawọn ọdọ atawọn mi in loun n ṣe.

No comments:

Post a Comment

Pages