Toyin Agbolade
Ileese Adrons ati ileese Capacious farms and food Ltd ni won jo sagbateru eto naa,to si je pe ileewe ogoji otooto lo kopa nibi ayeye idije'ayajo ojo onje'todun yii
Eto naa da lori 'ise agbe lojo iwaju kini afojusun re?ati ojuse onje lawujo ati bi a se le mojuto onje.
Oga agba ileese Capacious farms and food Chi Tola Robert so lojo naa pe,ise agbe wulo lawujo ati pe laisi agbe ko le si onje ti a le je fun idagbasoke.
O so lojo naa pe,odoodun ni eto yii yoo maa waye nibi tawon akekoo yoo ti maa dije lori oro onje ati bi ise agbe se wulo ti ileewe to ba yanranti yoo si gba ebun owo atawon ebun miiran .
Oludasile ileese Adrons,Aare Adetola Emmanuelking naa so lojo naa pe,pipada si orisun wa nidi ise agbe lo dara ti ileewe ADRONS Shimawa naa si kopa ninu idije naa.
Purofeso Adesegun to je alaga ileewe yunifasiti Babcock so lojo naa pe,idije yii yoo je kawon akekoo mo riri ise agbe ati onje ni awujo ati pe pelu ise agbe ,owongogo onje yoo dohun igbagbe.
Ni bayii,ileese Adrons ati ileese Capacious farm food Ltd ti seleri pe,odoodun ni ayeye ati eto idije yii yoo maa waye lati le je kawon akekoo ati awon ogo ojo ola orile ede yii mo pe,ife to dara lo le mu ise agbe ati eto onje gbooro lawujo wa.
No comments:
Post a Comment