Ọọniriṣa ṣeleri atilẹyin fun idije bọọlu ileeṣẹ ADRONS - TOYIN ALARIYA ONLINE NEWS

Iroyin Yajoyajo

ILEYA TI DE

ILEYA TI DE
ILEYA TI DE

Monday, October 21, 2024

Ọọniriṣa ṣeleri atilẹyin fun idije bọọlu ileeṣẹ ADRONS








Sande ogunjọ oṣu yii ni oludasilẹ ileeṣẹ ADRONS ,Aarẹ Adetọla Emmanuelking sabewo si aafin Ọọniriṣa,Ọba Adeyeye Ẹnitan Ogunwusi.
Ọba alade naa ti wa ṣeleri lati kun ileesẹ naa lọwọ ninu eto idije ere bọọlu afẹsẹgba ẹlẹẹkeje iru ẹ ti ileeṣẹ ADRONS ma n ṣe lọdọọdun.
Ibadan nipinlẹ Ọyọ ni idije naa yoo waye,to si jẹ pe odindi ọsẹ kan ni ilu Ibadan yoo fi gbalejo ninu oṣu kọkanla  to n bọ yii.
Aarẹ Adetọla to tun jẹ,Aarẹ Akilẹ Adimula Oodua fun Ọọniriṣa lẹbun bọọlu nla ti ọba alade naa si dupe lowo ileese Adrons paapaa fun atileyin won lasiko odun olojo to koja ati ayeye aadota odun Oonisha.
Aare Emmanuelking naa wa dupe lowo Oonirisha to gba won lalejo leyin ti ileese naa ti koko ko leta si Ori Ade pe awon fe sabewo si i
Boya iwo fe mo si i nipa ileese Adrons tabi o fe ra ile to fi ni lokan bale tete kan si ofiisi won to ba wa nitosi odo  e.

No comments:

Post a Comment

Pages