O mase o! Awon ololufe Seun Egbegbe ti koyin si i patapata - TOYIN ALARIYA ONLINE NEWS

Iroyin Yajoyajo

ILEYA TI DE

ILEYA TI DE
ILEYA TI DE

Wednesday, October 7, 2020

O mase o! Awon ololufe Seun Egbegbe ti koyin si i patapata

bee lo tun foju ba Ile ejo leyin odun keta l'ogba ewon


Omo jayejaye nni to tun je oludari Ile ise Ebony film,iyen Seun Egbegbe tun ti foju bale ejo lojo tuside ose to koja ti o si je kayeefi pe nise ni Ogbeni to je ore fun gbogbo awon olorin Fuji yii tun rewa koda nise ni awo ara re n dan ju ti tele lo.

Seun Abdulkareem gege bi oruko re la gbo pe ko ri oniduro lasiko ti isele naa sele si i iyen leyin ti ijoba atawon Mola to n se owo dola fesun jibiti kan an, beeni won so pe o ji foonu iPhone nigba naa, eyi lo mu Seun di ero ogba ewon kirikiri.

Agbejoro Seun be ijoba lati gba oniduro fun un,ti o si je ohun iyalenu pe titi di bi a se n so yii, a ko ri enikeni to le duro gege bii oniduro fun Seun to feran lati maa nawo lode ariya fun awon onitiata atawon olorin Fuji.

Agbejoro re iyen Ogbeni Adebayo Onifade fi ehonu re han lori iwa ti awon ololufe onibara re hu yii nipa gbigba gbe re si ogba ewon kirikiri ti ko si ri enikeni duro fun un gege bi oniduro pelu owo to le ni milionu marun ati pe oniduro naa gbodo je olugbe ilu Eko.

Sa o,Seun to je ololufe gbajumo osere tiata obinrin nni iyen Toyin Abraham nigba kan tun ti pada sinu ogba ewon kirikiri nibi to ti n jaye oloba ti won de tun ti sun igbejo si ojo kewa osu kokanla odun yii.

No comments:

Post a Comment

Pages