Oni gan an to n se ojo ojobo ni ese gbogbo awon sorosoro pe si Aafin Olu ti Itori iyen Oba Fatai Akamo, ti Oluaye fun gbogbo awon onifuji iyen Wasiu Ayinde to tun je Mayegun Ile Yoruba naa wa nibi ipade to waye nitori aawo to n sele laarin awon egbe FIBAN ati Wasiu Ayinde.
Gege bi a se gbo pe Olu Itori lo pe ipade yii lati pari ija gbigbona to sele laarin gbajumo sorosoro to n je Wole Sorunke eniti awon ti e n pe ni M c Murphy ati Oluaye.
Leyin ti kabiyesi gbo Oro enu awon mejeeji tan lo wa rawo ebe si won pe ija ko ni ere kankan ati pe ki egbe FIBAN labe Aare egbe won to n je Desmond Nwachukwu jebure, bee lo be Oluaye lati mase gba esu l'aye lati da aarin oun atawon sorosoro ru.
Te o ba gbagbe pe ose to koja ni iroyin naa gba igboro pe omoose Wasiu kan to n je K.C fi ese da pataani iya si ara M.C Murphy nibi ayeye ogota ojoobi Olu Itori to waye ni Agbegbe Ewekoro nipinle Ogun.
Eyi lo si mu egbe FIBAN be Alaafin ti ilu Oyo lati gba oye Mayegun Ile Yoruba lowo Wasiu, ti a si tun gbo pe egbe yii ti pase pe ki won mase lo orin Wasiu Lori redio mo.
Sa o,ija ti pari bayii to alaafia si ti joba,awon sorosoro to peju sibi ipade naa ni Soji Omotayo, Moji Eleja, Aare egbe FIBAN Ogbeni Desmond, atawon miiran.
No comments:
Post a Comment