Laipe yii ni egbe oselu alatako orile-ede yii, Peoples Democratic Party, PDP soro sita wi pe ki Gomina ipinle Eko, Babajide Sanwo-Olu ko'we fipo sile gege bi i gomina, ti won si ni ko kaju osuwon lai di gomina.
Bi iroyin naa se jade sita ni akowe ipolongo egbe oselu All Progressive Congress, APC n'ipinle Eko, Ogbeni Seyi Oladejo naa ti soro sita wi pe oro ti ko lese nile ni egbe PDP so jade sita, ti won si ni ko le di Sanwo-Olu lowo lati maa sise idagbasoke n'ipinle Eko.
O ni bo tile je pe ko seni ti nnkan to n sele nipinle Eko lati bi ose meloo kan seyin ko kan lominu, sibe o je ko di mimo pe awon nnkan naa ko ye ko je ohun ti won n ti oselu bo rara.
No comments:
Post a Comment