Gomina ipinle Ondo, Arakunrin Rotimi Akeredolu ti pariwo sita wi pe ko si Gomina kankan to toju awon ounje iranwo f'awon araalu, iyen Palliatives pamo sibikibi.
Laipe yii l'awon eeyan bere si i ja awon soobu nla-nla nibi ti won nigbagbo wi pe ijoba ko awon ounje iranwo to to s'awon araalu lasiko konilegbele fun ti ajakale arun Covid-19, ti won si bere si i ko orisirisi ounje to wa nibe.
Gbogbo gomina patapata ti oro yii kan ni won ti bere si i so orisirisi nipa awon ounje t'awon eeyan n ko naa, b'awon kan se n so pe awon ko ti i pin awon ounje naa tan, bee l'awon kan n so pe awon sese ra awon ounje naa ni.
Sugbon ninu oro Gomina Akeredolu t'ipinle Ondo, eni to tun je alaga egbe awon gomina ile Yoruba lo ti so pe igbimo kan to n sakoso eto pinpin awon ounje naa, iyen Coalition Against Covid-19 lo je ki pinpin awon ounje naa fale titi di asiko yii.
Gomina Akeredolu lo soro yii nibi ayeye odun keta ti Bisoobu ilu Owo fun ijo Church of Naijiria, Anglican Communion, iyen Omowe Stephen Fagbemi, eyi to waye ninu soosi All Saints Church to wa ni Idasen Owo, ipinle Ondo lana ti i se Aiku, Sande.
No comments:
Post a Comment