Asole Super Eagles Meji S'oju Ti Awon Omo Naijiria lojo kan soso - TOYIN ALARIYA ONLINE NEWS

Iroyin Yajoyajo

ILEYA TI DE

ILEYA TI DE
ILEYA TI DE

Monday, November 2, 2020

Asole Super Eagles Meji S'oju Ti Awon Omo Naijiria lojo kan soso


Afaimo ni ko ma je pe apo saka nla ni iko egbe agbaboolu orile-ede Naijiria, iyen Super Eagles yoo fi ko goolu wa sile leyin ti won ba koju iko egbe agbaboolu ti orile-ede Sierra Leone nibi idije to n bo laipe yii.

Opin ose to koja koja yii l'awon asole Super Eagles meji otooto, Daniel Akpeyi ati Maduka Okoye d'oju ti awon omo orile-ede Naijiria pelu bi won se pada sinu idije t'awon mejeeji wa.

Akpeyi la gbo pe won ko goolu meta le lowo ninu idije MTN8  to ti di ile mu egbe agbaboolu Kaizer Chief to koju egbe agbaboolu Orlando Pirates.

Okoye ni tie loun naa fi baago nla di goolu merin pada sile fun iko egbe agbaboolu Sparta Rotterdam ti won koju iko Heerenveen ninu idije Eredivisie to waye lojo Aiku Sande ana.

A tie gbo pe ki i se akoko ree ti Okoye yoo maa gba goolu merin ninu ifigagbaga kan.

TOJUBOLE gbo pe akonimo-n-gba Super Eagles, Gernot Rohr lo pe awon adilemu mejeeji yii fun idije ile adulawo to fee waye lorile-ede Sierra Leone lodun 2022.

Okan awon omo Naijiria ni ko ti i bale le awon asole mejeeji lori pelu bi won ko ti i se kaju osuwon to lati kopa ninu idije odun 2022 naa.

No comments:

Post a Comment

Pages