Laaro oni ti i se ojo Aje ti a mo si Monde lawon ara agbegbe Maraba to wa ni ilu Ilorin, iyen ipinle Kwara sadede ri oku kan nile, ti won o si ri ori lori oku naa.
Gbajugbaja ni eni ti won pa yii je ninu egbe okunkun, oruko re ni won pe ni Star Boy, eni ti won pa sinu ikolu awon omo egbe okunkun to waye laipe yii.
Awon meji la gbo pe won je ipe Olorun lakoko t'awon omo egbe okunkun latako meji otooto yii kolu ara won lati fi agba han ara won.
Opopona oju irin to wa nitosi Maraba la gbo pe won ti ri oku naa, eyi to mu k'awon to wa nitosi maa so orisirisi nipa isele naa.
Siwaju si i la tun gbo pe won tun sawari opolopo ori eeyan ninu baagi kan loju ona GRA to wa nilu Ilorin, ti ko si seni to le so b'awon ori oku naa se debe.
No comments:
Post a Comment