Loooto ni iroyin naa ti gba gbogbo igboro lati ose die seyin pe,awon okunrin meji lo n ja si akobi omo gbajumo olorin emi obinrin nni to n je Tope Alabi.
A gbo pe Maketa fiimu Yoruba kan to n je Olaoye ti so jade pe oun ni baba Ayomikun iyen akobi Tope ti o si tun so pe oun gan an ni oun se ikomojade omo naa ni adugbo Somolu nilu Eko.
O tun so pe aimoye awon Maketa iyen olokoowo fiimu lo peju sibi ikomojade naa.
O wa so pe o je iyalenu fun oun pe nise ni Tope gbe omo naa pamo fun oun latigba ti omo naa ti pe odun mewa,ti gbogbo ipa oun lati ri omo naa si ja si pabo. O tun so pe lojiji ni Tope tun paaro oruko omo oun si Alabi ti eyi si je ohun iyalenu fun oun.
Sa o, awon iranse Olorun meji kan ti side lati petu si aawo yii,Olori ijo Winners iyen Bisoobu Oyedepo ati baba Abiara ti ijo agbala itura ti so pe awon yoo yanju Oro yii sugbon ti Ogbeni Olaoye ti so pe oun setan lati se ayewo eje fun omo naa.
No comments:
Post a Comment