Obesere gba ami eye olorin Fuji to peregede ju fun odun 2020 - TOYIN ALARIYA ONLINE NEWS

Iroyin Yajoyajo

ILEYA TI DE

ILEYA TI DE
ILEYA TI DE

Friday, December 18, 2020

Obesere gba ami eye olorin Fuji to peregede ju fun odun 2020


Odun ayo ni odun yii je fun Alaaji Abass Akande Obesere eniti awon ololufe e mo si omorapala pelu bo se gba ami eye onifuji to dangajia ju laarin awon onifuji fun odun 2020.

Oba asakasa gba ami eye yii nilu Ibadan lose to koja,inu Gbogan Jorgor to wa nilu Ibadan ni ayeye igbami eye naa ti waye nibi ifami eye da awon eeyan lola eleekerin iru e iyen Pacesetter entertainment and recognition award(PERA) ni won ti fun oba asakasa ni ami eye yii.

Gege bi amugbalegbe Obesere se so fun tojubole pe eto idibo waye laarin Alaaji Saheed Osupa, Alaaji Taye Currency ati Alaaji Abass Obesere ,ti o si je pe Obesere lo jawe olubori pelu bo se je pe oun ni ibo re po ju gege bii onifuji to peregede ju.

Ogbeni Aremu ti gbogbo eeyan mo si Arems to je oludasile ileese Arems entertainment ti o tun je olowo otun Obesere so pe awo orin Abass to jade losu die seyin iyen'stand out' to mi gboro titi wa Lara amuye to je ki Obesere jawe olubori.

O tun so pe orin 'egungun becareful remix' naa wa lara orin to mu Omorapala gbegba oroke. 

Grandpa gege bi awon kan se tun n pe Obesere pelu bi omo re Suzan se bimo silu London lodun yii ti wa fi idunnu re han lori ami eye to gba naa.

.


No comments:

Post a Comment

Pages