O sele:Owo ijoba ti te awon odaran meji ti won n fi oruko Oba Elegushi jale Lori ero ayelujara - TOYIN ALARIYA ONLINE NEWS

Iroyin Yajoyajo

ILEYA TI DE

ILEYA TI DE
ILEYA TI DE

Friday, April 30, 2021

O sele:Owo ijoba ti te awon odaran meji ti won n fi oruko Oba Elegushi jale Lori ero ayelujara

Owo ijoba ipinle Eko ti te Ogbeni Moses Olaitan ati ikeji re to n je Segun Omoshola pelu esun pe awon mejeeji n fi oruko Oba Saheed Ademola Elegushi iyen Onikate ti ilu Ikate jale lori ero ayelujara fesibuuku.
Owo to le ni aadota milioonu lawon odaran yii gba lowo arabinrin kan lori ero ayelujara loruko Oba Elegushi,nigba ti Okan ninu won n ka boroboro bii aje nibe ni Moses ti je ko di mimo pe oun si fesibuuku loruko Oba alade naa ti oun si gbe foto re si i,ko pe pupo ni obinrin yii bere sii ni ba oun soro pe oun nife lati di Olori laafin oun,esekese ni oun so pe ko lo wa owo wa lati fi setutu ki o to o le di ayaba.
O so pe loju ese ni obinrin yii ti so pe ki oun so akanti ti oun yoo san owo si,lasiko yii ni oun pe ore oun to n je Segun lati wa akanti ti obinrin naa yoo san owo si,Segun si lo akanti re lati gba owo to le ni aadota milioonu lowo obinrin naa sugbon to pa iro fun oun pe milioonu meji pere ni obinrin yii san.Sa o,owo awon olopaa ijoba ipinle Eko ti te won,ti oga olopaa ipinle Eko iyen Ogbeni Hakeem Odumosu si fi idi isele naa mule lojo toside to koja lagbegbe Ikeja.


No comments:

Post a Comment

Pages