A gbo pe won ti bere etutu nilu Oyo bayii ,iroyin si to fi ye wa pe idile Agunloye ni yoo fa Oba tuntun sile sugbon ti Bashorun ilu Oyo iyen Oloye Yusuf Akinade yoo de Ile titi ti won yoo fi yan Alaafin Oyo tuntun.
Iroyin fi ye wa pe Alaafin ana naa ti n saisan lati bii ojo melo ti won si ti n seto lati gbe e lo si ilu oyinbo Koda tikeeti ti yoo fi fo ti wa nile pelu awon die ninu Olori re sugbon ti iku pada mu u lo lake ojo jimoh ose yii.
Ojo keedogun osu kewa odun 1938 ni won bi Alaafin ana si idile Alowolodu nilu Oyo to si je Alaafin lori ilu naa fun odun mejilelaadota.Osu die leyin iku Olubadan tele iyen Oba Saliu Adetunji ati Soun Ogbomoso oba Jimo Oyewunmi ni Alaafin naa tun w'aja.


No comments:
Post a Comment