Etaanu ko dara,eyin Yoruba e dibo fun Oloye Tinubu gege bii Aare---Alaaji Olaide Oladeebo Okadigbo - TOYIN ALARIYA ONLINE NEWS

Iroyin Yajoyajo

ILEYA TI DE

ILEYA TI DE
ILEYA TI DE

Tuesday, April 26, 2022

Etaanu ko dara,eyin Yoruba e dibo fun Oloye Tinubu gege bii Aare---Alaaji Olaide Oladeebo Okadigbo

Alaaji Olaide Oladeebo Okadigbo to je oludari ati oga fun Ajo to n ran awon alaini lowo iyen Okadigbo Foundation ti so pe Oloye Tinubu gan an ni Olorun yoo lo lati ko awa omo Orile ede yii de Ile ileri.O so pe Inu oun dun bi ijoba se si Boda iyen enuubode Kutonu sugbon ki ijoba je ki iresi dinwo ki awon mekunnu le ni anfani lati maa je iresi Kutonu nitori iresi Tiwa Lorile ede yii ko Dara to.
Okadigbo tun so pe ajo to n ran awon mekunnu lowo to je ti oun je Ajo to maa n fi Keke elese meta ati Oko korope ran awon eeyan lowo nipa tita a fun won ,ki won si maa sanwo ni diedie,bee lo so pe oun ni eni akoko ti yoo ko awon obinrin ni Eko lori bi won se le wa Keke napep ti eyi si ti je ki iwa odaran ati titoro baara kiri dinku ni Agege ati agbegbe re.
Omo Bibi ilu Apomu nipinle Osun ni baba oloju aanu yii,ileewe Yunifasiti ipinle Eko lo to kawe,bee lo feran Orin Fuji Wasiu Ayinde nitori orin olopo ni,omo odun die din ni Aadota ni Alaaji yii,bee lo so pe Inu oun yoo dun ti awon omo oun ba n se iru ise ti oun yan laayo yii.
O tun wa n dupe lowo ajo to n ri si irinna oko nipinle Eko iyen ministry of environment ati gbogbo awon ololufe re ,o ti wa so pe enikeni to fe mo nipa Ajo oun yoju si Ofiisi re to wa ni Agbegbe Agege.


No comments:

Post a Comment

Pages