Oko Labake Olojede gbajumo sorosoro Ori redio nilu Eko ku. - TOYIN ALARIYA ONLINE NEWS

Iroyin Yajoyajo

ILEYA TI DE

ILEYA TI DE
ILEYA TI DE

Wednesday, April 27, 2022

Oko Labake Olojede gbajumo sorosoro Ori redio nilu Eko ku.

Inu ibanuje ni Omolabake Olojede to je okan ninu awon sorosoro Ori gbajumo redio kan nilu Eko wa bayii pelu bi oko re se ku lorumoju ojo satide ati sannde ose yii.
Ayeye isinku yoo waye pelu Orin idagbere ni adugbo Ilasamaja nilu Eko lojo wesidee ose to n bo ni deede aago meji osan,iyen ojo kerin osu karun yii.Eto isinku yoo waye ni Ile re ladugbo olokemeji ni ijoko Ota ni ojo furaide iyen ojo kefa osu karun ni deede aago meje aaro ki ayeye idagbere to waye ni aago mewa Nile ijosin won ti ko jina si Ile Oloogbe.
Oloogbe fi Omo merin ati iyawo saye lo,nigba aye re oun ni Osi ilu ni ilu Akorogbo nijoba ibile Ewekoro nipinle Ogun,Oloogbe kawe ni Yunifasiti ilu Eko,bee lo je omo egbe Red Cross ati Boys Brigade.Adura wa ni pe ki Olorun te Oloogbe safefe ire.


No comments:

Post a Comment

Pages