Oloye Akintunde Ayeni to je Oludasile ati oludari ileese Yemkem ti pe ogota odun loke eepe,ti baba naa si ba egbe Akoroyin l'ede Yoruba iyen league of Yoruba media practitioner so awon iriri re nidi ise isegun ibile.
Oloye Ayeni je ko di Mimo pe,laye ojoun awon baba nidi ise isegun ibile ko ka ise iroyin ati ipolongo si rara loooto ni ,beba,redio ati amohunmaworan ko po bi I aye ode oni o sugbon won ko nigbagbo ninu ise iroyin rara eyi si mu abuku ba isegun ibile nigba naa
Yemkem to sayeye ogota odun laye so pe,odun 1981 iyen odun mejilelogoji seyin loun bere ise isegun ibile sugbon odun 1982 lawon eeyan bere si I ni mo oun daadaa,o so opo iriri re ati awon ipenija to salabapade sugbon ti Olorun pada gbe e leke
Yemkem tun salaye pe,oun ni onisegun ibile Akoko ti yoo Fi oogun ibile sinu kapsu(capsule)nitori oun lo wa imo Kun imo nipa isegun ibile nigba naa Koda tawon oyinbo alawo funfun mo riri ohun ti oun se yii,ti pupo ninu won si sabewo si oun lasiko yen,o so pe lati ara ohun yii gan an ni oruko inagije oun'Pathfinder ti jade.
No comments:
Post a Comment