Alaṣẹ ati oludasilẹ ileeṣẹ ADRONS iyẹn oloye Emmanuel King ti ki Akarigbo ti Rẹmọ,ọba Babatunde Adewale Ajayi CFR Torungbuwa keji ku oriire ọjọ ibi ọdun mọkanlelọgọta loke eepẹ.
Agbẹnusọ oludasile ileeṣẹ ADRONS nidi iṣẹ iroyin,ọgbẹni Ṣofowora Dapọ lo jẹ ko di mimọ pe,ileeṣẹ Adrons n gbooro si lasiko ti ọba Ajayi dori ipo gẹgẹ bii Akarigbo Rẹmọ nitori kabiesi maa n fẹ ilosiwaju awọn ọmọ bibi ilu Rẹmọ,Ololajulọ Emmanuelking nipasẹ agbẹnusọ rẹ sọ pe,onirẹlẹ,onisuuru ati alaanu eeyan ni ọba Ajayi.
Adura ọlọlajulọ Emmanuelking fun Akarigbo Rẹmọ ni pe,ki ẹmi kabiesi ṣe ọpọ ọdun laye ninu alaafia,owo ati ẹmi gigun,Api baide tuuuuu yuuuu sa.

No comments:
Post a Comment