Ayangbajumọ gbe eto nla kalẹ f'awọn agba onilu - TOYIN ALARIYA ONLINE NEWS

Iroyin Yajoyajo

ILEYA TI DE

ILEYA TI DE
ILEYA TI DE

Sunday, January 21, 2024

Ayangbajumọ gbe eto nla kalẹ f'awọn agba onilu


Lati ṣe koriya ati lati jẹ ki wọn mọ pe eeyan pataki ni wọn lawujọ,gbajumọ obinrin onilu nni Queen Eniola Lias Abiodun tawọn eeyan mọ si Ayangbajumọ ti gbe eto nla kan kalẹ fun awọn agba onilu ti wọn ti filu jẹun ,ti wọn si lulu fawọn ilu mọ-ọ-ka olorin,eto naa to pe ni Awọn Ayan-to-gbajumọ lo fi ṣe koriya fun awọn agba ọjẹ onilu naa ti wọn ti ṣe gudugudu meje ati yaaya mẹfa lagbo ariya.Eto ọhun ti wọn yoo maa ṣafihan ẹ lori ẹrọ ayelujara ati tẹlifiṣan ni Ayangbajumọ ti n fun awọn agba onilu naa lowo nla ati ẹbun to ṣe pataki si awọn agba onilu ọhun.
Ninu ọrọ ẹ,ni arẹwa obinrin naa to fi orilẹede Amẹrika ṣebugbe ti sọ pe,awọn baba yii ti jiṣẹ-jiya nidi iṣẹ ilu lilu bẹẹ lo jẹ pe awọn eeyan ki n fi bẹẹ ka awọn onilu kun gẹgẹ bi wọn ṣe maa n ṣe fawọn olorin 'ko digba tawọn baba yii ba ku ka to o mọ riri wọn ,o yẹ ka pọn wọn le lasiko ti wọn ṣi wa laye nitori ẹ la ṣe gbe eto Awọn 'Ayan-to-gbajumọ kalẹ.

No comments:

Post a Comment

Pages