Aarẹ Adetọla Emmanuelking ti gbe oṣuba sadankata fawọn osiṣẹ rẹ mẹwa to yanranti lọ soke okun ,orilẹ ede Tanzania lo ran won lo lai gba owo lọwọ wọn,o ṣe eyi lati mọ riri iṣẹ takuntakun tawọn oṣiṣẹ rẹ naa ṣe fun un lọdun to kọja
Eyi ki n ṣe igba akọkọ ti ogbontarigi oniṣowo ilẹ to tun jẹ oloye nilu Ijẹbu nipinlẹ Ogun maa fi ẹmi imoore han sawọn oṣiṣẹ ẹ,bẹẹ lo n ṣoore fawọn oniroyin kaakiri orilẹede yii pẹlu.
Ọfiisi rẹ to wa ni Ṣimawa lawọn oṣiṣẹ rẹ ti gbera lọ si papakọ ofurufu Muritala ti wọn yoo si balẹ gudẹ si agbegbe Zanzibar lorile ede Tanzania,bee ni Aarẹ Adetọla n bẹ awọn oṣiṣẹ rẹ yii lati jẹ aṣoju gidi fun ileeṣẹ ADRONS ni orile ede naa
No comments:
Post a Comment