Alaaji Rafiu Oseni Ẹlẹlẹ fawọn eeyan lẹbun onjẹ bi aawẹ Ramadan ṣe bẹrẹ - TOYIN ALARIYA ONLINE NEWS

Iroyin Yajoyajo

Adron Promo

Adron Promo
https://blog.adronhomes.com/promotional/

Monday, March 11, 2024

Alaaji Rafiu Oseni Ẹlẹlẹ fawọn eeyan lẹbun onjẹ bi aawẹ Ramadan ṣe bẹrẹ


Odu ni Alaaji Rafiu Oseni Ẹlẹlẹ jẹ paapaa laarin awọn ọdọ nipinlẹ rẹ,gẹgẹ bii iṣe rẹ lọdọọdun ati nigba gbogbo,o tun ti fi ẹbun onjẹ tọrẹ fawọn alaini bii oṣu Ramadan ọdun yii ṣe ti bẹrẹ,onjẹ bii iṣu,irẹsi,epo ati owo lo ti fun ọpọ awọn musulumi ododo lasiko yii ti wọn si ti n fi adura ranṣẹ si Ajagunpọtẹ fun ilu Igbein nipinlẹ Ogun
Anọbi Mowe gẹgẹ bii orukọ rẹ ti wa n bẹ awọn olowo ati bọrọkini lawujọ pe ki wọn ṣaanu awọn alaini lasiko ti ohun gbogbo ri bakan kaakiri orilẹ ede yii
Tẹ o ba gbagbe pe,ọsẹ to kọja lọ ni baba alaanu awọn mẹkunnu ko ọpọ onjẹ lọ fawọn ọmọ alailobi nile awọn ọmọ alailobi to wa nilu Ọta nipinlẹ Ogun lati fi sami ayẹyẹ ibi rẹ to wayè ṣugbọn to tun ti ṣe bẹbẹ mi in bayii nipa fifun awọn musulumi ni onjẹ lasiko oṣu alapọnle Ramadan

No comments:

Post a Comment

Pages