O dara ki ijoba maa gboriyin f'awon ọdọ orilẹ ede yii--Oluṣọ Ọladele Genesis - TOYIN ALARIYA ONLINE NEWS

Iroyin Yajoyajo

Adron Promo

Adron Promo
https://blog.adronhomes.com/promotional/

Wednesday, March 13, 2024

O dara ki ijoba maa gboriyin f'awon ọdọ orilẹ ede yii--Oluṣọ Ọladele Genesis


Oludasilẹ ijọ Genesis Global ti olu ijo won wa nipinle Eko,Oluṣọ Ọladele Isreal Ogundipẹ ti bẹ awọn ijọba wa paapaa labẹ iṣakosọ Aarẹ Bọla Ahmed Tinubu lati mọ riri awọn ọdọ orile ede yii nitori awọn ni ogo ọjọ ọla Naijiria.O sọrọ yii lẹyin ti awuyewuye kan ṣẹlẹ nipa ilẹ ti makẹta awọn olorin takasufe torukọ rẹ n jẹ Abu Abel ra si agbegbe Ọlọgọlọ Eti ọsa ni Lekki Ajah ipinlẹ Eko ṣugbọn tawọn alaṣẹ kan dide lojiji pe ,Ṣeyi Tinubu iyẹn ọmọ Aarẹ wa lo ni ilẹ naa lẹyin ti Abu ti san owo to yẹ lori ilẹ yii
Oluṣọ Genesis wa so pe,oun mo pe eeyan gidi ni Aare wa ,ati ogbeni Tayo Ayinde beeni omo Aare to je odolangba iyen Seyi Tinubu ki n se ika rara,toun si fe ki won tete wa nnkan se si oro ile naa,o so pe Abu Abel ti n jiya bo lati ojo pipe ati pe omo bibi ilu Remo nipinle Ogun yii je alaanu awon mekunnu ati olufe awon odo idi eyi lo se ye ki ijoba maa ki awon odo leyin ti won ba n se oriire nile abinibi won,eyi ki yoo je ki won gbero lati sa kuro ni orile ede won
Oluso wa so pe o dara kawon odo maa gbeja ara won pelu,ki won maa se ohun gbogbo ninu ife ati isokan lo dara.
.

No comments:

Post a Comment

Pages