Gbogbo eto lo ti to nilu Makun Omi nipinlẹ Ogun pẹlu bi ori ade ilu naa,Ọba Kazeem Adeshina Salami ṣe pe ọdun marun un lori itẹ awọn baba nla rẹ,ti gbajumọ ọba naa si tun fẹ fawọn eeyan pataki joye lawujọ
Gege bi atejise ti kabiesi fi sita pe ayẹyẹ yii ki n ṣe ọjọ kan rara,nitori awọn eto to wa nilẹ fun igbadun awọn ọmọ bibi ilu Makun omi pọ to si n bẹ awọn ọmọ bibi ilu rẹ loke okun lati wa yẹ ilu Makun omi si
Oluaye fuji ni olorin ti yoo dalubolẹ nibi ayẹyẹ naa ti ọpọ eto fun igbadun awọn ọdọ,atawọn bọrọkini yoo si waye pẹlu. 

No comments:
Post a Comment